Ọlámidé | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Ọlámidé Adédèjì |
Ọjọ́ìbí | 15 Oṣù Kẹta 1989 Bariga, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà |
Irú orin | Hip hop |
Occupation(s) | |
Instruments | Vocals |
Years active | 2011–present |
Labels | YBNL Nation |
Associated acts |
Ọlámídé Adédèjì tí a bí ní ọjọ́ Kéẹ̀dógún oṣù Kẹta,ọdún 1989 (15-3-1989), ní agbègbè Bàrígà ní Ìpínlẹ̀ Èkó tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlámidé Badoo tàbí BaddoSneh, jẹ́ gbajú gbajà olórin hip-hop, ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1][2] Ó jẹ́ olórin hip-hop tí ó ń akọrin pẹ̀lú àmúlù-ma la èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ní ọdún 2011, ó ṣe àgbéjáde àwo orin kan Rapsodi lẹ́yìn tí ó tọwọ́bọ̀wé Coded Tunes. YBNL, tó jẹ́ orin ẹlẹ́ẹ̀kejìrẹ̀ jáde lábẹ́ ẹgbẹ́ orin rẹ̀ "Yahoo Boy No Laptop" tí a tún mọ̀ sí YBNL Nation. Ní ọjọ́ keje oṣù kọkànlá, ọdún 2013, ó ṣe àgbéjáde àwo orin ẹlẹ́ẹ̀kẹta rẹ̀ Baddest Guy Ever Liveth. Orin àdákọ rẹ̀ "Durosoke" àti "Yemi My Lover" jáde nínú àwo orin náà. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù keje, ọdún 2013, Olamide jẹ́ olórinàkọ́kọ́ tó máa tẹwọ́ bọ̀wé pẹ̀lú Cîroc.[3]